List of Compounds & Oriki Idile
List of Compounds
OKE-AALA
1. ILE AALA,
2. ILE APONBI,
3. ILE OLUMOLE,
4. ILE AKOGUN,
5. ILE ABORISHA,
OKE-IDERA
1. ILE ASABA,
2. ILE AROKO
3. ILE OLOKO,
4. ILE OLUODE,
5. ILE AGIRI,
6. ILE ASURAMU,
7. ILE KUJENRA/OGUNSI,
8. ILE AKOREDE,
9. ILE LOKE,
10. ILE ISALE-ILALA
ISALE-TAA
1. ILE OLOBE,
2. ILE OGBO,
3. ILE ABORISHA,
4. ILE ERUWE,
8. ILE OLOMOH,
9. ILE ALAPO,
11. ILE ONIKILA,
12. ILE OJUTA,
13. ILE OLUKOYI,
14. ILE OKOLE,
15. ILE ISALE ODO,
16. ILE AJIWO,
17. ILE NANA,
18. ILE OLUMOLE,
19. ILE OLUAWO,
Due to civilization some compounds have changed their compound's names e.g Ile Panu is now called "Ile Okesuna" while Ile Aborisa is known as "Ile Onilu" etc.
Oriki Idile
1. OLUPO
OMO OLUPO ALA ELU
OMO ALAELU JOBA,OGUDU
OMO A HO LOHUN BI ILU IJESA
OMO OPERE OLUPO POOPO BI ENI GUNDO IDE
MO TA LALA MO JOYE MOJE
OMO EWEWE LASO IPO
FEREGEDE LASO AWON OYAN
OMO OLUPO ORIRA OBA DUDU IGBO EGII
SOBORO NIBGO EDU
OMO OYADOSIN OYADOLU
N’ILE ADEYEMI ADEOBA
OMO AKABIYI YOYINOYE
OLUPO ALAELU
OMO MOMU REFE MOMU KEMO
MO FERAN KAN LOGBO NILE ILALA
OPERE INA MESAN-PO
EFA N LAPON DANU
OMO EKULUKULU ABE OSUNSUN
EJA KULU ABE OMI
OPERE ONILAA JOGBO ILOSUN
OLA LAA JOGBO ODI
ABODE KENI REE JO GBAGEDE
GBAGEDE MI KIKI OYA
OPERE MO REWU SILE DOYE
MO ROSO A O MU
MO SINU L’OTI MO MU LOYIN
MO SEWO MO MU GBEWE
MO YAN ALE GBA NKAN YINMINI L’OYAN
E JE N F’OYA LODE IPO,BEE JE N F’OYA LODE IPO
E JE N FOKIN SAASI
E JE N FE MOGUNOLA ONIGBA ASO
ARABA ABIDI SOPO
ABIDI SOPO NI YOO GBA EGBAA WALE
OHUN E RI NI E FELEEGUN
OMO OLUPO AGBELEPERIN
OGUDU AHO LOHUN BI ILU IJESA
OBA TI BI WON LAJASE O WESE
PELA O WE KANINKAIN
AGIDI TI MO NI KII JEWU IYAN
NIJO ORUN YAA-LE L’AJASE
OLOYA N POYA,ONI PELA NPE PELA
ALAGIDI TI M’AGIDI E DANI
ASO N SE ROMI ROMI,EWU N SE WOMI PEERERE
KIJIPA ISALE ‘KOKO NSE BOO LOMI,BOO WOMI
O MOJU MI REE K’ODE
OMO OGAN SUBU OGAN DIDE
ALAURABI LO MO DIDIDE OGAN
NIJOTI OLUPO N W’OMO
OGUDU AJASE OLUPO KO R’OMO
WON WA OMO FAA O DILE BABALAWO
A FI GBA TI WON DE ‘DI OGAN
NI BABA WA TO D’OLOMO
OGUDU ARA AJASE AROSOLE KOMO O TO DE.
2. AALA
OMO AALA OOO
OMO ALEMU-LERA
OMO ARIJE MA GBAGBE ORE
ENI TO BA MOYE IRAWO
LO LE MO BI TI WON BI WA DE
OMO A DAKO NIBI EKUN GBE N RERI.
3. ASABA
OMO LAGOODO BABA ADEMU
OSORO NI BABA OJO
OJO NI KAWO OKITI AJIGBOTOLA EBI NII KAWO ALAGBARA
OMO ARU ‘KUTA L’AKORI,OMO A GBE ‘FA KARIDA
OMO ERO ONA N YASEE RIN
AFARA OKO N YAWO OKOO RO
OMO A BOSUPALA
OMO AFARA OKO
OMO AGBAGADA OKUTA
OMO A KO HANRU-HANRU E BA NI WON PE ASABA
OMO PAPA N JO OLE BUKO
OMO APATA PAARA PARA RE L’AJUBA
BABA MI N RETI ENITI O BU N KO
ERO ONA N YASEE RIN AFARA OKO N YAWO OKOOO RO
BI O GUN OKE ATO BI O R’OKA TO PO GOGO,OKO OYATOLA NI
OMO EWON NLA S’OBO RO
OMO AL’ETU LAGBE, OMO ARINA DAGBO
OMO OGIDAN IGBO OGIDAN NKO WON TAN NI ABI WON KU BE
OMO ISE O GBEKUN,EBI JARE OLE
OMO OBUN O TA GIRI S’OWO
OBUN TI KO TA GIRI S’OWO AMAA JOKO DE ‘SE
KO WO BI JABALA EBI TII JA MONI LARA
EYIN A SAGBE MO LELUBO N LE
E KA RELE AJIGBOTOLA E KA LO REE JE ‘GBE ISU
OMO ASABAA AGBALAGBA OYEE.
4. APONBI
OMO APONBI LOKE OMO AGARALOLU
OMO ALADE INA LERO IBON
EJE BARA NIYI OOGUN
OMO ALADE BOO LOPO OOGUN
BOO LEKE KO NI JE
ORO GBOGBO A SO DANU
OMO A SORO KELE BOJU WOGBE
IGBE KII RO ENI A WI FUN NI SEKU PANI
OMO MOLAOYE,OMO KUMONDERE
OMO KUKUNDUKU SEWE GERUGERU
OPO OOGUN ARUMO GALEGALE
OGUN TO KO JE EWE E NI KO PE
ORI BABA WA JE O JU EWE LO
ORI ALADE JE JU MUIBA LO
OMO BOO REKE O SEBI ENI RERENI
OMO GBOGBO A SO DANU
ORO ISEYIN KO Y’ALADE
OHUN A JO SO NI YENI
OMO ALADE KEE SIKA
BABA WA KEE BAKA GBELE
OMO A KOMO TIKA LEYIN
OMO A DURO GBOINGBOIN LEYIN A S’OTITO
OMO OLOHUN EKUNDUN
EJO PONRAN LOJU AGBO
OHUN DIDUN BI OLELE
OMO ONILE A-KOKAN
OMO ELYINKULE A A KO RORO
OMO OLOJUDE A A KO R’ELU ILORIN
5. ALAPA :
OMO ALAPA NI RAWE
ADEBIMPE OMO AGBORI OKA SEBO
ENINI OMO EJO MEJI
NINI SUNWON LEJO ARA N T’OKE SASA
NINI O NI O PAWODA KO GBE ‘SE RE L’OKE LOWO LAELAE
IYA MI NI O GBE LE LOWO
DAO OSERI OMO ASERI WOGBO OLUMODI
KIKI OLA LAPA
NININI LAA LORO L’APA
BERU BA NI OMO A MAA NI TIRE
IWOFA NI TIRE LOKE APA
ONI LEJOO RIN,OLA L’OKA O YAN
OMO EJOLA GBADE KO RESE YAN
OMO ALAPA O SI NLE WON JOYE KAN DUN O
MONAMONA NI WON FI J’ASIPA NI MODE
PARAMOLE A J’AROLE,
DUDU GBALAJA NAA FI J’OJOMU
AGBADU ROGBODO LO J’EESA LAPA
TERE GBALAJA LO J’OLUAWO
AWON OWORURU LO JE ‘LEMOSO ILU
ENINI OMO MEJI
OMO ALAPA OMO AJOYIN
AGBOLU OKA OMO AJOYIN
ENINI OMO ERE LAPA
OMO AJOYIN NI MAA JA
AIKOWO RIN EJO NIKU SE N PA WON LODAN-ODAN
BI OKA BA SIWAJU
TI PARAMOLE N TELE
KO SEEYAN TO LE DA OMO EJO LONA
ENINI REE OMO YANRIN LOMIDO
IKU O NI PAWA,ARUN O NI GBE WA DE MOLE.
6. SAO (IGBETI)
SAO AWONGA
OMO ONIBU EJA
KIKI ODO AKASA
IGBIN N SEBO KODO O MAMA GBE
OKASA N SEBO KODO O MAMA FA
ATIGBIN AT’OKASA LA O FI J’ORUNLA NILE DEBUDEGBO
OMO MO DEBU JI N TO PEJA
MO DE ‘GERE SUNWON L’EYO
OMO SAO OLOKE MERINDINLOGUN
SAO AWONGA
OMO ONIBU EJA
EYIN LOMO ONIGBETI OMO ASOYE SOORU
TO TILE IGBARO WA,MONILOLA OMO EKUN LORI OKE
IJI ELEYO OMO EYO
OMO AFEFE TI SOKO WELEWELE
PAMU MO BAWON NAJA LEYO
OKE META OTOTO NI NBE NILE ARA IGBETI GBOGBO WON LO LORUKO
OKAN NBE NIBE WON A JEKURU FUNFUN
OKAN NBE NIBE WON A JAKARA
OKAN NBE NIBE WON A JEWOWO
OMO IGBETI,ASOYE SOORU
OKE META OTOTO TI N BE NIGBETI GBOGBO WON LO LORUKO
OKAN NSE BI OTUTU,OKAN NSE BI OYE,
OKAN NSE BI ORU
MONILOLA OLOMI TUTU ESE OKE.
7. ONIRESA
AGBE OLOLA,OMO JALA TI OLUGBON BI
OMO OTUN ABE OMO OSI KOLA
OMO OLORI KOLA TI N BE LALADE OYO
OMO ALABE LAPO,OMO ASAGBE GBOWO
OMO AGBE REKETE S’OMO NITAN,
OMO OYINBO IDI OGUN
OMO A DOYI KALE ALADODO RAINRAIN
MA DOYI KAMI LEKULE MO MO TI DADODO MI
OMO OKUTA RIGIDI LO KOMI LESE LADEGUN
MO SUBU YEGE MO TENU BOGBA ELEPO,
MO FAGBON ISALE BUYO LALO
KAKA K’ELEPO O NAMI OWO EPO NI N O YAA SAN
OMO FENI SEPO NI BI RESA NINU
WOLE O BUPO NI YA MODE LARA
ARESA DUDU LEGBON PUPA LABURO
BATA LAAJO NIRESA ILE,
E WO AYA ARESA BO TISE GBADUN BATA JO
INA SUN A O M’AKO,INA SUN A O M’ABO
INA ABUTU ELEGBEEDOGBON ABE,AGBE ARA IRESA
NIRESA,NIRESA GBOGBO MODE NIRESA NI LEE.
8. OLUAWO (OROLU) :
E TETE JEMI NI TEPA OJE
ADELAWE SE PELE,OMO EIYE TI N SUNKUN ORI ATE
MO LULU OOSA SIYAN LAWE
ONIDE POKI OROLU N O MOKA EGBEJE
ABAJA POKI N O MA RAYI EGBEFA
EGBEJI OLOOGUN MOKO MO ROJE NILE AKINLEFUN
AKINLEFUN OROLU N O MAA FOJE SEYE
TORI PE O TUN MI O LODE BEENI OSI MI O LO BABA
TOTUNTOSI NI N SUNKUN OJE WUMI NILE AKINLEFUN
MO GBE KIRINJINJIN MNILE AKINLEFUN
IYA FUNMI LASO TONI GELE TORI MO FE LO REE WORAN
AFIN WA RI MI LOJA O A MI LORE
ABUKE ILE WA RIMI LOJA O LEMI TUTU
O TUN DELEEKEJI,IYA FUN MI LASO T’ONI GELE
TORI MO FE LODE,MO TUN GBO KIRINJINJIN NILE AKINLEFUN
AFIN WA RIMI LOJA O BOMI LOWO
ABUKE ILE WON TE OMO LEMI LOWO DENDE,
ADIE Y’OGUN ADIE P’OGUN WON L’ADIE O POMO RE
ADIE Y’OGBON ADIE P’OGBON WON L’ADIE O POMO RE
WON GB’ADIE TA WON FOWO R’EIYELE
EIYELE OROLU YE MEJI O PAKAN SOSO
AWA LOMO MOJE OKUTA RO SINSIN,MOJE GBONGBO RIMI SINSIN LAWE
OKA N DARI KENI MOMO A O ROGUN,EBO LOLUFUNADE MU WON SE
OROLU KEYI LAGBADUN,MO LENI LE MO SUN LEEKAN
MO LEPO NLE MO JE FUNFUN
ORISA OROLU MO NIYO MO JE ATE
MO LEPO NLE MO F’OMI JESU NILE GBOWO ADE OROLU
AWA NI ILA L’ADE WA MI O KOWO R’ADE
OMO EJE LE WA GBA LAA DELE MO
OGUN JE OGUN O JE N O GBOWO EJE MI DANDAN
AWA LOMO EJE LAWA GBA LA O SA RELE MO
OMO ORI ADE OJOPERE,OJO PA EWA MI RODODO
OJO PA ABAJA SILO LEGBE OTUN NILE GBOWO ADE
OOSA TI NBE NILE OROLU ALADO
JEKI N BAWON J’ATE KIJE.
9. EDU (OGOGO OLOYOKUN)
OMO JOLUBARI TIDI REKU
TIDIREKU A BEGUN EGBERE
OMO ATORI KE NAMU-NAMU NISAN
ATI KEKERE M’AWO
OMO MOIN-MOIN META APINNI
OLELE MEFA LAGBURE
PAKA JE MEJI-MEJI MOIN-MOIN TAN NINU IGBA ATOKUN BABA KO RIJE
ONIKALUKU N WO RAWO LABE ASO
OMO OTI PON KANKAN AMU MU ORO PAN KANKAN A YESE
BENIYAN Y’ESE ORO YIO Y’OSE OTI NILE OLUBARI
OGOGO MO ERU KAN OLELE
OGOGO MO A TIDIREKU OMO A TI KEKERE MAWO
OGOGO ARA ELEMELE
OMO ATI KEKERE MOJO AWO
SAMBE-SAMBE OGOGO A KU MO SORUN OGBORI
OMO O RI KO SI NINANINA MI KO JO
OMO O RI DENA TAN INA MI JO GEERE
OMO O RI FITILA FELENJU TANNA
OMO O RI SOGBON SUN OMO EPO SOGBON YO
OMO ALASO LERE,ABASOO JOKA
OMO BULENIWON,ABASOO ROJU
OMO OSOBINSOBI
OMO OSOBINSOBI
OMO TANI O SOBI KEGUNGUN FO NINU IGBO
OMO ARIBU WOLE
OMO OLOGUN AIYE
OMO OGBONGBO KAN, OMO OLULU KAN
MI O LE FOGBO PARA MI KO MA DORI AJA
OMO AREKU, OMO AREKU
OMO AREKU DOJA MA KUTA
OMO OGOGO ARA OYOMOKO
OMO A TI KEKERE JE BABA
NI OYOMOKO,BABA BABA NIWON PE RA WON NINU ILE WON
OMO OLOYOKUN
OMO OPE TO MII SAWO
DANDA NI MO DAGUNU LABURE OJE
OMO OKU ERIN JA O GBAGBO
ALAYE EFON JA O GBODAN
KEEKEEKEE O FORI JA O GBINBERI
BI WON FE BANI JA LOFORI WON A DASO BOJU
WON A NI O N SIN EGUNGUN JE
BI WON KO NI BANI JA LOFORI WON A DASO BOJU
WON A NI BABA N KI O
BABA N KI O KO BAA WAYE
AIYE NI BABA FI WON SI KO TO BA TIE LO
OMO MOIN-MOIN META APINNI,OLELE MEFA LABURE OJE
IWO JEJI KEMI O JEJIKI T’ATOKUN O OPARA
OMO EGUNGUN SOWO GENGE LABE ASO.
10. SIYANBOLA
SIYANBOLA OLUKUEWU
LADIGBOLU OLUKUEWU
IKU BABA YEYE
ORO OMO ATIBA
OMO O SORO SORO SEEGUN
OMO AKANNI TI N SORO TI N PARUN
SIYANBOLA OLUKUEWU
OLUKUEWU GBAMI,SIYANBOLA GBAMI,LADIGBOLU GBAMI
ABOWO GBOGBOGBO TI Y’OMO RE LOFIN
SIYANBOLA YOMI OOO,LADIGBOLU YOMI.
11. ILE OKOLE (Supplied by Kamal Adebayo)
OMO ONIRE OSIN
OMO AKEYEMU IRE MO GUN OMO AMUIE SHORO OMO ABULE SHO WO,
IRE O SEJE KE MI O POKO MI WA LE,
POKO MI WA LE ARA LOKUNRIN,
MO SAKO MO DA BI ABO MOSE SOWO ETE REGDEKEJI,
SE BI IRAN BABA YIN NI ROO SELE KO YINBO TODE,
OYINBO DE TAN OWO NA TUN POSI NI,
BIO SI ONIRE UN OROKO,
BIO SI ONIRE UN O YENAI,
AWON BABA YIN, LON PE NI OMO AKAN LEKUN MO TA GIRI,
TORI PE WON NI BIO SE ENI WAYA OWO AJE ENI WA SAN
.......To include the names of your compounds, please send a mail to: [email protected]

Click here to try again.